Yoruba Hymn APA 280 - Mimo, mimo, mimo! Olodumare

Yoruba Hymn APA 280 - Mimo, mimo, mimo! Olodumare

 Yoruba Hymn  APA 280 - Mimo, mimo, mimo! Olodumare

APA 280


1. Mimo, mimo, mimo! Olodumare!

 Ni kutukutu n’ iwo o gbo orin wa;

 Mimo, mimo, mimo! Oniyonu julo!

 Ologo meta lai Olubukun!


2. Mimo, mimo, mimo! Awon t’orun nyin,

 Nwon nfi ade wura won lele y’ ite ka:

 Kerubim, Serafim nwole niwaju Re,

 Wo t’ O ti wa, t’ O si wa titi lai.


3. Mimo, mimo, mimo! b’ okunkun pa O mo,

 Bi oju elese ko le ri og Re,

 Iwo nikan l’O mo, ko tun si elomi,

 Pipe ‘nu agbara ati n’ ife.


4. Mimo, mimo, mimo! Olodumare!

 Gbogbo ise re n’ ile l’ oke l’ o nyin O;

 Mimo, mimo, mimo! Oniyonu julo,

 Ologo meta, lai Olubukun!


 APA II


1. Mimo, mimo, mimo, Olodumare!

 Baba, Omo, Emi, Eleda Oloto;

 Mimo, mimo, mimo, olododo julo!

 Pipe ’nu iwa, lai Olubukun.


2. Mimo, mimo, mimo, gbogbo aiye gberin,

 Korin ’yin: k’ aiye yin Eni Metalokan,

 Olorun Alagbara, Olorun Olufe,

 Olupamora, Olore ofe.


3. Mimo, mimo, mimo; Olodumare!

 Ogo, Ola, Ogbon, Agbara ni Tire;

 Mimo fun Eni Mimo ti o gunwa,

 “Eleru ni iyin, Eni yanu.” Amin.



Yoruba Hymn  APA 280 - Mimo, mimo, mimo! Olodumare

This is Yoruba Anglican hymns, APA 280- Mimo, mimo, mimo! Olodumare   . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post