Yoruba Hymn APA 263 - Kukuru l’oj’ aiye wa

Yoruba Hymn APA 263 - Kukuru l’oj’ aiye wa


Yoruba Hymn  APA 263 - Kukuru l’oj’ aiye wa

APA 263


1. Kukuru l’oj’ aiye wa,

 Die l’ojo aro;

 Aiye ti ko l’opin mbe,

 Nibit’ ekun ko si.


2. A! ere wo l’o to yi:

 Isimi ailopin;

 At’ ile nla t’o dara,

 F’elese bi awa.


3. L’aiye yi awa njagun,

 L’orun a o d’ade,

 Ade ti ki dibaje,

 Ti y’o ma dan titi.


4. Nibe l’awa o gbe ri

 Enit’ a gbekele:

 Iye awon to ba mo,

 Ni yio je tire.


5. Owuro ojo n ambo,

 Okunkun y’o ka lo,

 Awon olokan pipe

 Y’o ma ran bi orun.


6. Olorun at’ ipin wa,

 N’nu ekun ore Re,

 Nibe ni a o ma wo

 A o yin lojukoju.


APA II


1. A! ilu daradara,

 Mo fe lati ri o,

 Opolopo ni nsunkun

 Fun ’fe lati ri O.

 Ogo ti mbe ninu re,

 Ororo ni f’okan,

 Egbogi ni fun aisan,

 Ife ni, iye ni.


2. Ibugbe kansoso na,

 Paradise ayo,

 Nibit’ omije ki de,

 Erin ni ’gbagbogbo;

 Odagutan ti a pa,

 On ni ewa ibe;

 Awon ti a rapada

 Nkorin ibukun Re.


3. Okuta jasper didan,

 L’a fi mo odi re;

 Oniruru okuta

 L’a fi te ita re;

 Ilu na dara pupo,

 O mo bi kristali;

 Awon mimo ni ngbe ’be,

 Kristi n’ Ipile re.


4. Okun ti ko n’ebute,

 Ojo ti ko n’opin;

 Orisun ’tura didun,

 Fun awon alare.

 L’or’ Apat’ aiyeraiye

 L’a mo odi re si;

 Tire l’ade asegun,

 Tire l’ade wura. Amin. 


Yoruba Hymn  APA 263 - Kukuru l’oj’ aiye wa


This is Yoruba Anglican hymns, APA 263 -  Kukuru l’oj’ aiye wa . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post