Yoruba Hymn APA 255 - Jerusalem t’ orun
APA 255
1. Jerusalem t’ orun,
Orin mi, ilu mi!
Ile mi bi mba ku,
Ekun ibukun mi;
Ibi ayo!
Nigbawo ni,
Ngo r’ oju re,
Olorun mi?
2. Odi re, ilu mi,
L’ a fi pearl se l’ oso;
’Lekun re ndan fun ’yin,
Wura ni ita re!
Ibi ayo, &c.
3. Orun ki ran nibe,
Beni ko s’ osupa;
A ko wa iwonyi,
Krist n’ imole ibe.
Ibi ayo, &c.
4. Nibe l’ Oba mi wa,
T’ a da l’ ebi l’ aiye;
Angeli nkorin fun,
Nwon si nteriba fun.
Ibi ayo, &c.
5. Patriark’ igbani,
Par’ ayo won nibe;
Awon woli, nwon nwo
Omo alade won.
Ibi ayo, &c.
6. Nibe ni mo le ri
Awon Apostili;
At’ awon akorin,
Ti nlu harpu wura,
Ibi ayo &c.
7. Ni agbala wonni,
Ni awon Martir wa;
Nwon wo aso ala,
Ogo bo ogbe won.
Ibi ayo &c.
8. T’ emi yi sa su mi,
Ti mo ngb’ ago Kedar!
Ko si ’ru yi loke:
Nibe ni mo fe lo.
Ibi ayo, &c.
Yoruba Hymn APA 255 - Jerusalem t’ orun
This is Yoruba Anglican hymns, APA 255 - Jerusalem t’ orun . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals