Yoruba Hymn APA 224 - Ji, ji, okan ayo, ji, ji
APA 224
1. Ji, ji, okan ayo, ji, ji,
Oluwa re jinde:
Lo boji Re, k’o si mura
Okan ati korin:
Gbogbo eda l’o si ti ji,
Ti nwon nkorin didun,
Itanna ’kini t’o ko tan
Leba odo lo hu.
2. Isudede aiye y’o lo
L’ojo ajinde yi,
Iku ko si mo n’nu Kristi,
Iboji ko n’ ipa;
Ninu Kristi l’a nwa, t’a nsun,
T’a nji, t’a si ndide,
Omije t’iku mu ba wa
Ni Jesu y’o nu nu.
3. Ki gbogb’eiye ati igi
At’ itanna ti ntan,
Ki nwon so ti isegun Re,
Ati t’ajinde Re.
Papa, e gbohun nyin soke,
E bu s’orin ayo?
Enyin oke, e si gberin
Wipe, ’Iku ti ku.’
4. Okan ayo, e ji, e wa
Oluwa t’o jinde;
E yo ninu ajinde Re,
K’oro Re tu nyin n’nu,
E gbohun nyin soke, k’ e yin
Enit’o ji dide;
L’ohun kan ni ka gberin pe,
“Jesu jinde fun mi” Amin.
Yoruba Hymn APA 224 - Ji, ji, okan ayo, ji, ji
This is Yoruba Anglican hymns, APA 224- Ji, ji, okan ayo, ji, ji . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals