Yoruba Hymn APA 217 - L’ owuro Ojo Ajinde

Yoruba Hymn APA 217 - L’ owuro Ojo Ajinde

 Yoruba Hymn  APA 217 - L’ owuro Ojo Ajinde

APA 217

1. L’ owuro Ojo Ajinde.

 T’ara t’okan y’o pade,

 Ekun, ’kanu on irora

 Y’o dopin.


2. Nihin nwon ko le sai pinya,

 Ki ara ba le simi,

 K’o si fi idakeroro

 Sun fonfon.


3. Fun ’gba die ara are yi

 L’a gbe s’ ibi ’simi re;

 Titi di imole oro

 Ajinde.


4. Okan t’o kanu nisiyi,

 To si ngbadura kikan,

 Y’o bu s’orin ayo l’ojo

 Ajinde.


5. Ara at’ okan y’o dapo,

 Ipinya ko ni si mo;

 Nwon o ji l’aworan Kristi, ni

 ’Telorun.


6. A! ewa na at’ ayo na

 Y’o tip o to l’ Ajinde!

 Y’o duro, b’ orun at’ aiye

 Ba fo lo.


7. L’oro ojo ajinde wa,

 ’Boji y’o m’ oku re wa;

 Baba, iya, omo, ara

 Y’o pade.


8. Si ’dapo ti o dun bayi,

 Jesu masai ka wa ye;

 N’nu ’ku, ’dajo, k’a le ro m’a

 ’Gbelebu. Amin.



Yoruba Hymn  APA 217 - L’ owuro Ojo Ajinde

This is Yoruba Anglican hymns, APA 217- L’ owuro Ojo Ajinde  . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post