Yoruba Hymn APA 194 - Gbogb’ ogo, iyin, ola
APA 194
1. Gbogb’ ogo, iyin, ola,
Fun O, Oludande,
S’ eni t’ awon omode
Ko Hosanna didun!
‘Wo l’ Oba Israeli,
Om’ Alade Dafid,
T’ O wa l’ Oko Oluwa,
Oba Olubukun.
Gbogb’ ogo, iyin, ola,
Fun O, Oludande,
S’ Eni t’ awon omode
Ko Hosanna didun.
2. Egbe awon maleka
Nyin O loke giga;
Awa at’ eda gbogbo
Si dapo gberin na.
Gbogb’ ogo, iyin, ola, &c.
3. Awon Hebru lo saju,
Pelu imo ope:
Iyin, adua, at’ orin,
L’ a mu wa ‘waju re.
Gbogb’ ogo, iyin, ola, &c.
4. Si O saju iya Re,
Nwon korin iyin won:
‘Wo t’ a gbega nisiyi,
L’ a nkorin iyin si.
Gbogb’ ogo, iyin, ola, &c.
5. ‘Wo gba orin iyin won:
Gb’ adura t’ a mu wa,
‘Wo ti nyo s’ohun rere,
Oba wa Olore.
Gbogb’ ogo, iyin, ola, &c.Amin.
Yoruba Hymn APA 194 - Gbogb’ ogo, iyin, ola
This is Yoruba Anglican hymns, APA 194 - Gbogb’ ogo, iyin, ola . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals