Yoruba Hymn APA 167 - Ki se l’ainireti
APA 167
1. Ki se l’ainireti
Ni mo to wa;
Ki se l’aini ’gbagbo
Ni mo kunle:
Ese ti gori mi,
Eyi sa l’ ebe mi, Eyi sa l’ebe mi,
Jesu ti ku.
2. A ! ese mi poju,
O pon koko !
Adale, adale,
Ni mo nd’ ese !
Ese aiferan Re;
Ese aigba O gbo; Ese aigba O gbo;
Ese nlanla !
3. Oluwa mo jewo
Ese nla mi;
O mo bi mo ti ri,
Bi mo ti wa;
Jo we ese mi nu !
K’ okan mi mo loni, K’ okan mi mo loni,
Ki ndi mimo.
4. Olododo ni O
O ndariji;
L’ese agbelebu
Ni mo wole;
Je k’ eje iwenu,
Eje Odagutan, Eje Odagutan,
We okan mi.
5. ’Gbana, Alafia
Y’o d’ okan mi;
’Gbana, ngo ba O rin,
Ore airi;
Em’ o f’ ara ti O,
Jo ma to mi s’ ona, Jo ma to mi s’ ona,
Titi aiye. Amin.
Yoruba Hymn APA 167 - Ki se l’ainireti
This is Yoruba Anglican hymns, APA 167- Ki se l’ainireti . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.