Yoruba Hymn APA 157 - Bi mo ti kunle, Oluwa

Yoruba Hymn APA 157 - Bi mo ti kunle, Oluwa

Yoruba Hymn  APA 157 - Bi mo ti kunle, Oluwa

APA 157 

1. Bi mo ti kunle, Oluwa,

 Ti mo mbe f’ anu lodo Re,

 Wo t’ Ore ’lese ti nku lo,

 Si tori Re gb’ adura mi.


2. Ma ro ’tiju at’ ebi mi,

 At’ aimoye abawon mi,

 Ro t’ eje ti Jesu ta ’le,

 Fun dariji on iye mi.


3. Ranti bi mo ti je Tire,

 Ti mo je eda owo Re;

 Ro b’ okan mi ti fa s’ ese,

 Bi ’danwo si ti yi mi ka.


4. A ! ronu oro mimo Re,

 Ati gbogbo ileri Re;

 Pe ’Wo o gbo adua titi,

 Ogo Re ni lati dasi.


5. A ! ma ro ti ’yemeji mi,

 Ati ailo or’ofe Re;

 Ro ti omije Jesu mi,

 Si fi ’toye Re di temi.


6. Oju on eti Re ko se,

 Agbara Re ko le ye lai:

 Jo wo mi: okan mi wuwo,

 Da mi si, k’ O ran mi lowo. Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 157 - Bi mo ti kunle, Oluwa. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post