Yoruba Hymn APA 154 - A f’ ayo ro ore-ofe
APA 154
1. A f’ ayo ro ore-ofe
T’ Alufa giga wa,
Okan Re kun fun iyonu,
Inu Re nyo fun ’fe.
2. Tinutinu l’ o ndaro wa,
O mo ailera wa;
O mo bi idanwo ti ri,
Nitori o ti ri.
3. On papa l’ ojo aiye Re,
O sokun kikoro;
O mba olukuluku pin
Ninu iya tin je.
4. Je ki a f’ igbagbo ’rele
W’ anu at’ ipa Re;
Awa o si ri igbala,
L’ akoko iyonu. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 154 - A f’ ayo ro ore-ofe . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.