Yoruba Hymn APA 145 - Elese;-- mo nfe ’bukun
APA 145
1. Elese;-- mo nfe ’bukun;
Onde;-- mo fe d’ ominira;
Alare;-- mo nfes’simi;
“Olorun sanu fun mi.”
2. Ire kan emi ko ni,
Ese sa l’o yi mi ka,
Eyi nikan l’ ebe mi,
“Olorun sanu fun mi.”
3. Irobinuje okan !
Nko gbodo gboju s’oke;
Iwo sa mo edun mi;
“Olorun sanu fun mi.”
4. Okan ese mi yi nfe
Sa wa simi laiya Re:
Lat’ oni, mo di Tire:
“Olorun sanu fun mi.”
5. Enikan mbe lor’ ite;
Ninu Re nikansoso
N’ireti at’ ebe mi:
“Olorun sanu fun mi.”
6. On o gba oran mi ro,
On ni Alagbawi mi;
Nitori Tire nikan,
“Olorun sanu fun mi.” Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 145- Elese;-- mo nfe ’bukun . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.