Yoruba Hymn APA 133 - E fi oju iyonu wo
APA 133
1. E fi oju iyonu wo
Okun ile Keferi:
Sa wo bi opolopo won
Ti njowere ’nu ese;
Okunkun bo, Okunkun bo,
Oju ile aiye wa.
2. Imole eni okunkun,
Dide, mu ibukun wa !
Imole f’ awon Keferi
Wa, pelu ’mularada;
Ki gbogb’ Oba, Ki gbogb’ Oba
Wa sinu imole na.
3. Je k’ awon Keferi ti mbo
Igi ati okuta;
Wa lati fi oribale
Fun Olorun alaye
Je k’ ogo Re, Je k’ ogo Re,
Bo gbogbo ile aiye.
4. Iwo t’ a f’ ipa gbogbo fun,
Soro na ! pa ase Re;
Je ki egbe oniwasu
Tan ’ruko Re ka kiri;
Wa pelu won, Wa pelu won,
Oluwa, titi d’ opin. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 133 - E fi oju iyonu wo . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.