Yoruba Hymn APA 130 - Gbo orin ’yin dida aiye
APA 130
1. Gbo orin ’yin dida aiye,
T’ egberun orile nko,
Orin didun bi omi pupo
“Bukun, ogo, ipa, ’gbala
Fun Olorun lor’ite,
Baba, Omo, Emi Mimo
Olola ’lainipekun.”
2. Titi lo, lat’oro d’ale,
Lor’olukuluku ’le,
Lat’ opolopo enia,
Ilu alawo pupa,
’Lawo dudu t’ a da n’ide,
Funfun ti o po niye,
Omnira alarinkiri
De ’le awon Arabu.
3. Lati ebute otutu
De ile ti o moru,
Awon olokan gbogbona
Leba okun Pasifik,
Lat’opo aimoye okan
Onigbagbo alayo,
Awon to nsona bibo Re,
Nwon fere de Sion na.
4. Akojo orile-ede,
Lat’ inu eya ahon,
Gbo, nwon nkorin iyin titi,
Gbo orin ologo ni,
O b’afonifoji mole,
O sin dun lori oke,
O ndun siwaju tit’ o fi
Kun ibugbe Olorun.
5. Gbo, didun orin na dapo
Mo orin awon t’orun,
Awon t’o koja n’nu ’danwo
Sinu isimi loke,
Nwon wo aso ailabawon,
Imo ’segun lowo won,
Nwon nfi duru ko Hosanna,
Ni’waju Olorun won.
6. “ Ogo fun Enit’ o few a,
T’ O we wa n’nu eje Re,
K’oba, alufa, ma korin
Si Baba, Olorun wa.
K’enia mimo on Angeli,
Ko Alleluia titi:
A segun orun apadi:
Olodumare joba.” Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 130 - Gbo orin ’yin dida aiye . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.