Yoruba Hymn APA 128 - Eni t’ o joko low’ otun
APA 128
1. Eni t’ o joko low’ otun
Ti Baba l’ oke orun,
On na l’ o si mbebe fun wa
Nitori k’ a ba le la.
2. O mbebe, k’ a ba le gba wa
Lowo Oludanwo ni;
Ati n’nu ese, on ’binu
At’ idajo ti mbowa.
3. O mbebe k’ a ba le jogun
Ile ti Oba orun;
Tani l’ aiye, t’ o le rohin
Ogo ati ola na.
4. On nikan ni Alagbawi
Fun awon eni Tire;
Eje enikeni ko le
Pa igbese t’ a je re.
5. Iwo nikan l’ Omo Baba
Iwo l’ Oba titi lai;
Enia j’ elese pupo;
Angeli ni ’ranse Re.
6. Iwo si je Olododo
T’ o pe lodo Baba Re;
Be gege ni oruko Re
Gbogbo ileri y’o se. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 128 - Eni t’ o joko low’ otun . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.