Yoruba Hymn APA 103 - Kabiyesi ! Isun ’bukun
APA 103
1. Kabiyesi ! Isun ’bukun
Oba, Baba araiye;
Keferi r’ore-ofe gba
Nwon si nwo agbala Re;
Awa wole, awa dupe,
A n’ ipo n’nu Ijo Re;
A nf’ igbagbo woo go Re,
A nyin ore-ofe Re.
2. A ti jina, O si pe wa
Sunmo ite mimo Re:
A dapo n’nu majemu Re
T’ilaja, t’irapada.
Amoye, ni ila-orun,
Ri ’rawo anu tin tan
Ijinle t’o sin latijo
Ijinle ’fe Olorun.
3. Kabiyesi; Olugbala,
Keferi mu ore wa:
Ni tempili Re l’a nwa O,
Jesu Krist’ Oluwa wa;
K’ara, okan, at’ emi wa
Wa fun iyin Re nikan;
K’a le jogun ilu Ogo,
K’a si ma yin O titi. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 103 - Kabiyesi ! Isun ’bukun . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.