Yoruba Hymn APA 102 - B’ awon ara igbani

Yoruba Hymn APA 102 - B’ awon ara igbani

 Yoruba Hymn  APA 102 -  B’ awon ara igbani

APA 102

1. B’ awon ara igbani

 Ti f’ ayo ri ’rawo na;

 Bi nwon ti f’ inu didun

 Tele ’mole didan re;

 Be, Oluwa Olore

 Ni k’a mu wa d’odo Re.


2. Bi nwon ti fi ayo lo

 Si ibuje eran na;

 Ti nwon si wole nibe

 F’ Eni t’orun t’aiye mbo;

 Gege be ni k’a ma yo

 Lati wa s’ ite anu.


3. Bi nwon ti mu ore wa

 Si ibuje eran na;

 Be ni k’ awa ma f’ ayo

 Mimo t’ese ko baje

 Mu ’sura wa gbogbo, wa

 Sodo Re, Jesu Oba.


4. Jesu mimo, pa wa mo,

 L’ona toro l’ojojo;

 ’Gbat’ ohun aiye ba pin,

 M’okan wa de ilu, ti

 ’Rawo ko nsamona mo;

 ’Biti nwon nwo ogo Re.

 

5. Ni ’lu orun mimo na,

 Nwon ko wa imole mo;

 ’Wo l’Orun re ti ki wo;

 ’Wo l’ayo at’ ade re;

 Nibe titi l’ao ma ko

 Halleluya s’Oba wa. Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 102 - B’ awon ara igbani  . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post