Yoruba Hymn APA 100 - Alakoso ti orun
APA 100
1. Alakoso ti orun,
Alanu at’ Ologbon;
Igba mi mbe lowo Re,
Opin gbogbo l’ase Re.
2. Ase Re l’o da aiye
Ati ibi mi pelu;
Obi, ile, on igba;
Nipa Re ni gbogbo won.
3. Igb’ aisan, on ilera,
Igba ise on oro;
Igba ’danwo, ibinu,
Igba ’segun, iranwo.
4. Igba iridi Esu
Igba ’to ’fe Jesu wo,
Nwon o wa, nwon o si lo,
B’ Ore wa orun ti fe.
5. Iwo Olore-ofe,
’Wo ni mo f’emi mi fun,
Emi jewo ife Re,
Emi teriba fun O. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 100 - Alakoso ti orun. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.