Yoruba Hymn APA 79 - Ojo ayo nlanla na de
1. Ojo ayo nlanla na de,
Eyi t’ araiye ti nreti;
Nigbat’ Olugbala w’ aiye
Nigbat’ a bi ninu ara.
2. Olusagutan ni papa
Bi nwon tin so agutan won,
Ni ihin ayo na ko ba.
Ihin bibi Olugbala.
3. Angel iranse Oluwa
L’ a ran si won, alabukun,
Pelu ogo t’ o tan julo,
Lati so ihin ayo yi.
4. Gidigidi l’ eru ba won,
Fun ajeji iran nla yi;
“Ma beru” l’ oro iyanju
T’ o t’ enu Angeli na wa.
5. A bi Olugbala loni;
Kristi Oluwa aiye ni;
N’ ilu nla Dafidi l’ o wa,
N’ ibuje eran l’ a te si.
6. “Ogo fun Olorun” l orun
Ti enia y’o ko s’ orun;
Fun ife Re laini opin,
T’ o mu Alafia w’ aiye. Amin.
Yoruba Hymn APA 79 - Ojo ayo nlanla na de
This is Yoruba Anglican hymns, APA 79 - Ojo ayo nlanla na de . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.