Yoruba Hymn APA 56 - Jesu t’ o ga julo l’ orun
APA 56
1. Jesu t’ o ga julo l’ orun,
Ipa Re l’ o d’ aiye;
’Wo f’ ogo nlanla Re sile,
Lati gba aiye la.
2. O w’aiye ninu irele
Ni ara osi wa;
Nitori k’ okan t’ o rele
Le t’ ipase Re la.
3. Wiwa Re ya angel l’enu,
Ife t’ o tobi ni;
Enia l’ anfani iye
Angeli se, ko ni.
4. Nje araiye yo; san yin de,
E ho iho ayo:
Igbala mbo fun elese;
Jesu, Olorun ni.
5. Oluwa, je ki bibo Re,
Nigba erinkeji,
Je ohun ti a nduro de,
K’ o le ba wa l’ ayo. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 56 - Jesu t’ o ga julo l’ orun. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.