Yoruba Hymn APA 37- Didun n’ise na, Oba mi
APA 37
1. Didun n’ise na, Oba mi,
Lati ma yin oruko Re,
Lati se ’fe Re l’ owuro,
Lati so oro Re l’ ale
2. Didun l’ ojo ’simi mimo,
Lala ko si fun mi loni:
Okan mi, ma korin iyin
Bi harpu Dafidi didun.
3. Okan mi o yo n’ Oluwa,
Y’o yin ise at’ oro Re
Ise ore Re tip o to !
Ijinle si ni imo Re.
4. Emi o yan ipo ola
’Gb’ ore-ofe ba we mi nu
Ti ayo pupo sib a mi,
Ayo mimo lat’ oke wa.
5. ’Gbana, ngo ri, ngo gbo, ngo mo
Ohun gbogbo ti mo ti nfe;
gbogbo ipa mi y’o dalu
Lati se ’fe Re titi lai. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 37 - Didun n’ise na, Oba mi. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.